Thursday, February 23, 2017

yoruba prayer


Adura yoruba

Baba wa ti nbe li orun
Mt3:17 Ohun kan lati orun wa ti o wi pe
eyiyii ni Ayanfe omo mi
Eni ti inu mi dun si gidigidi
Mt4:4 nko fe wa laye nipa akara nikan
emi fe wa laye nipa gbogbo oro ti o ti enu Olorun jade wa
Mt4;6 nko fe be sile fun ara mi
Mt4:7 nko fe dan Oluwa Olorun mi wo
Mt4:9 nko fe wole fun satani
Nko fe foribale fun satani
Mt4:10 emi fe ki satani pada lehin mi
pada lehin mi, satani
Oluwa Olorun mi ni mo fe foribale fun
Oluwa Olorun mi nikansoso ni mo fe maa sin
Mt4:11 fi mi sile, satani
emi fe ki awon angeli se iranse fun mi
Mt4:17 mo fe ronupiwada
Mt4:19 mo fe to Jesus lehin
Mo fe ki Jesu so mi di apeja enia
Mt4:25 mo fe ki opolopo enia to Jesus lehin
Mt5:3 mo fe ni ijoba Olorun
Mt5;4 mo fe maa kaanu
Mo fe ki Olorun tu mi ninu
Mt5:5 mo fe ki okan mi tutu
Mo fe jogun aiye
Mt5:6 mo fe tele ododo
mo fe yo
Mt5:7 mo fe je alaanu
Mo fe ri aanu gba
Mt5:8 Mo fe ki inu mi funfun
emi fe ri Olorun
Mt5:9 emi fe je onilaja
emi fe ki a ma a pe mi ni omo Olorun
Mt5:12 mo fe maa yo
emi fe kun fun ayo
emi fe ki ere mi po li orun
Mt5:13 emi ni iyo aiye
Nko fe di obu
Adun ni mi
emi fe nilaari
Nko fe ki a da mi nu
Nko fe di itemole ni atelese eniyan
Mt5:14 Emi ni imole aiye
Ori oke ni mo wa
Mi o le farasin
Mi o fe farasin
Mt5:15 fitila ni mi
Mi o le wa labe osuwon
Ori opa fitila ni mowa
emi nfi imole fun gbogbo eniyan ti nbe ninu ile
Mt5:16 emi fe je ki imole mi ki o mole to bee niwaju eniyan
emi fe ki awon eniyan maa ri ise rere mi
emi fe ki awon eniyan maa yin baba mi ti nbe li orun logo
Nko fe ro pe Jesu wa lati pa ofin run
Nko fe ro pe Jesus wa lati pa awon woli run
Mt5:19 nko fe ru okan kikini ninu ofin Olorun
Nko fe ko awon eniyan lati ru ofin Olorun
Mt5:20 emi fe ki ododo mi koja ododo awon akowe ati ti awon farisi
emi fe de ijoba orun
Mt5:21 nko fe paniyan
Mt5:22 Nko fe binu
nko fe wa ninu ewu idajo
nko fe wa ninu ewu igbimo
Nko fe wa ninu ewu ina orun apaadi
Mt5:23 nko fe ki arakunrin mi ni ohun kan ninu si mi
Mt5:24 emi fe koko ba arakunrin mi laja
Mt5:25 nko fe ki ota mi fi mi le onidajo lowo
Nko fe ki a gbe mi so sinu tuubu
Mt5:26 emi fe jade kuro ninu tuubu
Mt5:27 Nko fe se pansaga
Mt5:28 nko fe wo obinrin kan lati se ifekufe si i
Nko fe se pansaga ni okan mi
Mt5;29 emi fe yo ikose ti o wa ni oju mi jade
emi fe so ikose ti o wa ni oju mi nu
emi fe ki ikose ti o wa ni eya ara mi segbe
Nko fe ki a gbe gbogbo ara mi ju sinu ina orun apadi
Mt5:30 nko fe ki owo mi mu mi kose
emi fe ge Ikose ti o wa ni owo mi kuro
Mt5:31 nko fe ko aya mi sile
Nko fe mu aya mi se pansaga
Nko fe gbe eni ti a ko sile ni iyawo
Mt5:34 nko fe bura rara
Nko fe fi orun bura
Mt5:35 nko fe fi aiye bura
Mt5:36 nko fe fi ori mi bura
Mt5:37 nko fe so oro ti o wa nipase ibi
Mt5:41 emi fe ba eniti o fi agbara mu mi lo si ibuso kan, de ibuso meji
Mt5:42 emi fe fi fun eniti o bere lowo mi
Nko fe mu oju kuro lodo eni ti o nfe ya lowo mi
Mt5:43 nko fe korira awon ota mi
Mt5:44 emi fe sure fun awon eni ti o nfi mi re
emi fe soore fun awon ti o korira mi
emi fe gbadura fun awon ti nfi arankan ba mi lo
emi fe gbadura fun  awon ti nse inunibini si mi
Mt5:48 emi fe pe gege bi baba mi ti nbe li orun ti pe
Mt6:9 Baba wa ti nbe ni orun
Ki a bowo fun oruko re
Mt6:10 Ki ijoba re de
Ife tire ni ki a se, bii ti orun, bee ni ni aye
Mt6:11 Fun wa ni onje oojo wa loni
Mt6:12 Dari gbese wa ji wa, bi awa ti ndariji awon onigbese wa
Mt6:13 Ma se fa wa sinu idewo,
sugbon gba wa lowo bilisi
Nitori ijoba ni tire, ati agbara, ati ogo, laelae
Ni oruko Oluwa jesu kristi
Rev1:8 Alfa ati Omega
Ipilese ati opin
Eni ti o nbe, ti o ti wa, ti o si nbowa
Olodumare
Rev1:17 eni isaaju ati eni ikehin
Rev1:18 eni ti o nbe laaye si i titi lae
Eni ti o ni kokoro iku ati ti isa -oku
Jn17:11 baba mimo, pa mi mo, loruko re
Jn17:12 Ma je ki nsegbe
Jn17:13 Je ki ayo Jesu ni imuse kikun ninu emi tikarami
Jn17:15 pa mi mo kuro ninu ibi
Jn17:17 So mi di mimo ninu otito
Otito ni oro re





No comments:

Post a Comment